IDAYEPADA SI IPILẸ

A kọ iwe yii pẹlu itọsọna ẹmi mimọ. Opin “ika aye atọwọda” ti sun mọ itosi. Aye ipilẹ yii jẹ afihan bi Ọlọrun ṣe fẹ ka gbe lori ilẹ. Pataki ọmọ eniyan ni ko mu ki ohun gbogbo ti Ọlọrun da tubọ buyi si i, eleyii ki i ṣe nipa ti owo o bi ko ṣe lati gbe igbesi aye to ń tan ayọ ati idunnu kari ohun gbogbo. Itọsọna fun idapada aye si bo ṣe wa nipilẹ yii mẹnu ba gbogbo isọri ti a fi ń gbe aye wa – latori eto oṣelu, to fi mọ eto ọrọ-aje, titi dori ijamba awujọ to dorikodo ti gbogbo aye ti ń jiya labẹ ẹ latọdun yii.

Ninu aye ipilẹ yii, ipilẹ ẹtọ ọmọniyan ni pe ẹnikẹni ko gbọdọ gbe ninu ìṣẹ́, ẹni kan ko si ga ju ẹni kan ninu iyi rẹ lawujọ. Gbogbo orilẹ-ede yoo wa lẹgbẹẹ ara wọn bi irọ ni, ọkan ninu wọn ko si ni i laṣẹ lati ki ẹnu bọ ọrọ oṣelu orilẹ-ede keji koda bi wọn ba pe e pe ko waa da si i.
Iṣẹ ńla lati sun awọn orilẹ-ede aye kuro nipo to wa yii lọ si ipilẹ wa lọwọ awọn agbaagba orilẹ-ede kọọkan. Awọn ọmọ orilẹ-ede kọọkan ni yoo yan awọn agbaagba wọnyi ki wọn le bu ninu omi ọgbọn gbogbo araalu, ko si le han pe ifẹ araalu ni wọn ń ṣe.

Eto ijọba ninu aye ipilẹ yii yoo wa lọwọ awọn Agba Ilu ti awọn ọmọ ilu yoo yan lati ri i daju pe akoso ilu ṣe deede pẹlu ifẹ araalu. Ninu igba tuntun to ń bọ yii, akoso ilu ko ni i si lọwọ ọba tabi olorì, ẹgbẹ oṣelu kan ko si ni i le da si i. Ọwọ awọn agbaagba to jẹ aṣoju araalu yii ni akoso ilu yoo wa ti wọn oo si maa fi omi ọgbọn wọn dari ilu. Awọn agbagba yi yatọ si awọn ti a ma yan lati ṣe ijọba. Gbogbo awon eto iselu ti wa ni Abala Keerin. Ki a se ayewo re daradara.

Awọn iwe ajọsọ tuntun mi-in to jinlẹ ninu eto aye yoo waye lati pe igba ọtun yii wọle. Awọn iwe ajọsọ to faaye gba ajọgbe alaafia, ibọwọ-funra-ẹni, dida ilẹ pada fawọn ọmọ onilẹ, ifopin si aawọ ati ikọja aaye si aala orilẹ-ede mi-in. Gbogbo awọn ajọsọ to wa laaarin awọn orilẹ-ede atọwọda nǹi, awọn ajọsọ to fẹsẹ mulẹ ninu imọ-tara-ẹni-nikan, gbogbo rẹ ni yoo wa sopin latinu oṣu kejila ọdun 2023.
Ọlọrun mọ pe ọmọ araye ati awọn orilẹ-ede ki i fẹẹ gbọ tabi gba ikilọ, paapaa awọn ikilọ to wa latọdọ Rẹ. Sibẹ, O ṣi ń fi ọrọ ran awọn eeyan si wa pẹlu ireti pe a oo gbọ ikilọ ki awọn ajalu buruku le fo wa da. A ti ri ọṣẹ́ ti ogun ati ìṣẹ́ ń ṣe, ẹda ọwọ eniyan lawọn mejeeji yii.
Ogun agbọtẹlẹ ki i pa arọ to ba gbọn o. Ẹ jẹ ka tẹti si ohun Ọlọrun.

30.00

Share

About author

Òkọ̀wé náà jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ tí ó ní àkókò pẹ̀lú ìfẹ́ fún ayé tó dára níbi tí àlàáfíà àti òmìnira kúrò lọ́wọ́ òṣì ti ń jọba. Ó ti ṣe àfihàn èyí láti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún sẹ́yìn nípasẹ̀ ìrànwọ́ àwùjọ rẹ̀ sí àríyànjiyàn, àpérò àti àwọn ìdánilẹ́kọ̀ọ́ lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó níí ṣe pẹ̀lú ìṣàkóso, ìṣèlú àti ìdàgbàsókè àwùjọ.

Reviews

There are no reviews yet.

Only logged in customers who have purchased this book may leave a review.

Hello again!

We use cookies to ensure you get the best experience on our website. cookie policy